Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 39:9-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Mo dákẹ́ jẹ́ẹ́;èmi kò sì ya ẹnu mi,nítorí wí pé ìwọ ni ó ṣe é.

10. Mú ìnà Rẹ̀ kúrò ní ara mi;èmí ṣègbé tán nípa ìlù ọwọ́ Rẹ.

11. Ìwọ fi ìbáwí kìlọ̀fún ènìyàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀,ìwọ a mú ẹwà Rẹ parunbí kòkòrò aṣọ;nítòótọ́ asán ni ènìyàn gbogbo.

12. “Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa,kí o sì fetí sí igbe mi;kí o má ṣe di etí Rẹ sí ẹkún minítorí àlejò ni èmi lọ́dọ̀ Rẹàti àtìpó, bí gbogbo àwọn baba mi ti rí.

13. Dá mi sí, kí èmi lè ní agbára,kí èmi tó lọ kúrò níhín-ín yìí,àti kí èmi ó tó ṣe aláìsí.”

Ka pipe ipin Sáàmù 39