Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 38:17-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Nítorí tí mo ti ṣe tán láti ṣubú,ìrora mi sì wà pẹ̀lú mi nígbà gbogbo.

18. Mo jẹ́wọ́ ìrékọjá mi;àánú sì ṣe mí fún ẹ̀ṣẹ̀ mi.

19. Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá miláì ní ìdí pàtàkì, wọ́n lágbára púpọ̀,ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ókórìírá mi lọ́nà òdì.

20. Àwọn tí wọn ń fiibi san rere fún miàwọn ni ọ̀ta minítorí pé mò ń tọ ire lẹ́yìn.

21. Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀,ìwọ Olúwa!Ọlọ́run miMá ṣe jìnnà sí mi

22. Yára láti ràn mí lọ́wọ́, Olúwa,Olùgbàlà mi.

Ka pipe ipin Sáàmù 38