Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 38:13-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Ṣùgbọ́n mo dàbí adití odi,èmi kò gbọ́ ọ̀rọ̀;àti bí odi, tí kò le sọ̀rọ̀.

14. Ní tòótọ́,mo rí bí ọkùnrin tí kò gbọ́ràn,àti bí ẹnu ẹni tí kò sí ìjiyàn.

15. Ṣùgbọ́n sí ọ Olúwa,ìwọ ni mo dúró dè;ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run mi,ẹni tí yóò dáhùn.

16. Nítorí tí mo gbàdúrà,“Gbóhùn mi, kí wọn má ba à yọ̀ mí;nígbà tí ẹsẹ̀ mi bá yọ̀wọn yóò máa gbé ara wọn ga sí mi”.

17. Nítorí tí mo ti ṣe tán láti ṣubú,ìrora mi sì wà pẹ̀lú mi nígbà gbogbo.

18. Mo jẹ́wọ́ ìrékọjá mi;àánú sì ṣe mí fún ẹ̀ṣẹ̀ mi.

Ka pipe ipin Sáàmù 38