Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 38:12-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Àwọn tí n wá ẹ̀mí midẹ okùn sílẹ̀ fún mi;àti àwọn tí ó fẹ́ pa mí lárań sọ̀rọ̀ nípa ìparun,wọ́n sì ń gbérò ẹ̀tàn ní gbogbo ọjọ́.

13. Ṣùgbọ́n mo dàbí adití odi,èmi kò gbọ́ ọ̀rọ̀;àti bí odi, tí kò le sọ̀rọ̀.

14. Ní tòótọ́,mo rí bí ọkùnrin tí kò gbọ́ràn,àti bí ẹnu ẹni tí kò sí ìjiyàn.

15. Ṣùgbọ́n sí ọ Olúwa,ìwọ ni mo dúró dè;ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run mi,ẹni tí yóò dáhùn.

16. Nítorí tí mo gbàdúrà,“Gbóhùn mi, kí wọn má ba à yọ̀ mí;nígbà tí ẹsẹ̀ mi bá yọ̀wọn yóò máa gbé ara wọn ga sí mi”.

17. Nítorí tí mo ti ṣe tán láti ṣubú,ìrora mi sì wà pẹ̀lú mi nígbà gbogbo.

Ka pipe ipin Sáàmù 38