Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 38:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. OlúwaMá ṣe bá mi wí nínú ìbínú Rẹ,bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe fi ìyà jẹ mínínú ìrunú Rẹ̀.

2. Nítorí tí ọfà Rẹkàn mọ́ mi ṣinṣin,ọwọ́ Rẹ sìkì mí mọ́lẹ̀.

3. Kò sí ibi yíyè ní ara à minítorí ìbínú Rẹ;kò sí àlàáfíà nínú egungun minítorí i ẹ̀ṣẹ̀ mi.

4. Nítorí àìṣedédé miti borí mi mọ́lẹ̀;wọ́n tó ìwọ̀n bi àjàgàtí ó wúwo jù fún mi:

5. Ọgbẹ́ mi ń rùnó sì díbàjẹ́nítorí òmùgọ̀ mi;

6. Èmi ń jòwèrè:orí mi tẹ̀ ba gidigidièmi ń sọ̀fọ̀ rìn kiri ní gbogbo ọjọ́.

7. Nítorí ẹ̀gbẹ́ mi kún fún ìgbóná ti ń jó nikò sì sí ibi yíyè ní ara mi,

8. Ara mi hù, a sì wó mi jégéjégé;mo ké rora nítorí ìrúkèrúdò àyà mi.

9. Olúwa,gbogbo a áyun mi ń bẹ níwájú Rẹ;ìmí ẹ̀dùn mi kò sá pamọ́ fún ọ.

10. Àyà mi ń mí hẹlẹ,agbára mi yẹ̀ mí sílẹ̀bí ó ṣe ti ìmọ́lẹ̀ ojú mi ni,ó ti lọ kúrò lára mi.

11. Àwọn ọ̀rẹ́ miàti àwọn ẹlẹgbẹ́ midúró lókèèrè rérékúrò níbi ìpọ́njú mi,àwọn alábàágbé é mi,dúró lókèèrè.

Ka pipe ipin Sáàmù 38