Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 37:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ìwọ dákẹ́ jẹ́ ẹ́ níwájú Olúwa,kí o sì fi sùúrù dúró dè é;má ṣe ṣe ìkanra nítorí àwọntí ń rí rere ní ọ̀nà wọn,nítorí ọkùnrin náà ti múèrò búburú ṣẹ.

8. Fàsẹ́yìn nínú inúbíbí,kí o sì kọ ìkannú sílẹ̀.Má ṣe ṣe ìkanra,nítorí pé ó gbéni sí búburú pẹ̀lú.

9. Nítorí pé á ó gé àwọn ènìyànbúburú kúrò,Ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá dúró de Olúwaàwọn ni yóò jogún ilẹ̀ náà.

10. Ṣíbẹ̀ nígbà díẹ̀ síi,,àwọn ènìyàn búburú kì yóò sí mọ́nítòótọ́ ìwọ yóò fi ara balẹ̀wo ipò Rẹ̀,wọn kì yóò sí níbẹ̀.

11. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútùni yóò jogún ilẹ̀ náà,wọn yóò sì máa ṣe inú dídùnnínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.

Ka pipe ipin Sáàmù 37