Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 37:25-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Èmi ti wà ni èwe,báyìí èmí sì dàgbà;ṣíbẹ̀ èmi kò ì tíi rí kia kọ olódodo ṣílẹ̀,tàbí kí irú ọmọ Rẹ̀máa ṣagbe oúnjẹ.

26. Aláàánú ni òun nígbà gbogboa máa yá ni;a sì máa bùsí i fún ni.

27. Lọ kúrò nínú ibi,kí o sì máa ṣe rere;nígbà náà ni ìwọ gbé ní ilẹ̀ náà títí láéláé.

28. Nítorí pé Olúwa fẹ́ràn ìdájọ́ òtítọ́,kò sì kọ àwọn ènìyàn mímọ́ Rẹ̀ sílẹ̀.Àwọn olódodo ni a ó pamọ́títí ayérayé,ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ènìyàn búburúní a ó ké kúrò.

29. Olódodo ni yóò jogún ilẹ̀ náà,yóò sì máa gbé ibẹ̀ títí ayérayé.

30. Ẹnu olódodo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,ahọ́n Rẹ̀ a sì máa sọ̀rọ̀ ìdájọ́.

31. Òfin Ọlọ́run Rẹ̀ ń bẹní àyà wọn;àwọn ìgbẹ́sẹ̀ Rẹ̀ kì yóò yẹ̀.

32. Ènìyàn búburú ń ṣọ́ olódodo,Ó sì ń wá ọ̀nà láti pa á.

33. Olúwa kì yóò fi lé e lọ́wọ́kì yóò sì dá a lẹ́bi,nígbà tí a bá ń ṣe ìdájọ́ Rẹ̀.

34. Dúró de Olúwa,kí o sì má a pa ọ̀nà Rẹ̀ mọ́,yóò sì gbé ọ lékèláti jogún ilẹ̀ náà:Nígbà tí a bágé àwọn ènìyàn búburú kúrò ìwọ yóò ri.

35. Èmí ti rí ènìyàn búburútí n hu ìwà ìkà,ó sì fi ara Rẹ̀ gbilẹ̀ bíigi tútù ńlá.

36. Ṣùgbọ́n ní ìṣẹ́jú kan síi ó kọjá lọ,sì kíyèsí, kò sì sí mọ́;bi ó tílẹ̀ jẹ́ wí pé mo wá a kiri,ṣùgbọ́n a kò le è ri.

37. Má a kíyèsí ẹni pípé,kí o sì wo adúró ṣinṣin,nítorí àlàáfíà ni òpin ọkùnrin náà.

Ka pipe ipin Sáàmù 37