Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 37:17-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Nítorí pé a ó ṣẹ ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú,ṣùgbọ́n Olúwa gbé olódodo sókè.

18. Olúwa mọ àwọn ọjọ́ àwọn adúró ṣinṣin,àti wí pé ilẹ̀ ìní wọn yóò wà títí ayérayé;

19. Ojú kì yóò tì wọ́n ní àkókò ibi,àti ní ọjọ́ ìyàn, a ó tẹ́ wọn lọ́rùn.

20. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú yóò ṣègbé,àwọn ọ̀ta Olúwa yóò dà bíẹwà oko tútù;wọn fò lọ;bi èéfín ni wọn yóò fò lọ kúrò.

21. Àwọn ènìyàn búburú yá,wọn kò sì san-án padà,ṣùgbọ́n àwọn olódodo a máa fi fún ni;

22. Nítorí àwọn tí Olúwa bá bùkúnni yóò jogún ilẹ̀ náà,àwọn tí ó fi bú ni a ó gé kúrò.

23. Ìlànà ìgbésẹ̀ ènìyàn rere wáláti ọ̀dọ̀ Olúwa wá,o si ṣe inú dídùn sí ọ̀nà Rẹ̀;

24. Bí ó tilẹ̀ ṣubúa kì yóò ta á nù pátapáta,nítorí tí Olúwa di ọwọ́ Rẹ̀ mú.

25. Èmi ti wà ni èwe,báyìí èmí sì dàgbà;ṣíbẹ̀ èmi kò ì tíi rí kia kọ olódodo ṣílẹ̀,tàbí kí irú ọmọ Rẹ̀máa ṣagbe oúnjẹ.

Ka pipe ipin Sáàmù 37