Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 37:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Má ṣe ìkanra nítorí àwọnolùṣe búburú,kí ìwọ má sì ṣe ṣe ìlàra nítorí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀;

2. nítorí pé wọn yóò gbẹbí koríko,wọn yóò sì Rẹ̀ dànùbí ewéko tútù

3. Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa,kí o sì máa ṣe rere;torí pé ìwọ yóò gbé ilẹ̀ náà,kí o sì gbádùn ààbò Rẹ̀

4. ṣe inú dídùn sí Olúwa;òun yóò sì fún ọ níìfẹ́ inú Rẹ̀.

5. Fi ọ̀nà Rẹ lé Olúwa lọ́wọ́;gbẹ́kẹ̀lée pẹ̀lú,òun yóò sì ṣe é.

6. Yóò sì mú kí òdodo Rẹ̀ jádebí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ,àti ìdájọ́ Rẹ̀ bí ọ̀sán gangan.

7. Ìwọ dákẹ́ jẹ́ ẹ́ níwájú Olúwa,kí o sì fi sùúrù dúró dè é;má ṣe ṣe ìkanra nítorí àwọntí ń rí rere ní ọ̀nà wọn,nítorí ọkùnrin náà ti múèrò búburú ṣẹ.

Ka pipe ipin Sáàmù 37