Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 36:5-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ Rẹ,ìwọ Olúwa,ó ga dé ọ̀run,òtítọ́ ọ̀ Rẹ ga dé àwọ̀sánmà.

6. Òdodo Rẹ dàbí àwọn òkè Ọlọ́run,àwọn ìdájọ́ Rẹ dàbí ibú ńlá;ìwọ gba ẹranko àti ènìyàn là, Olúwa.

7. Báwo ni ìṣeun ìdúróṣinṣin ìfẹ́ Rẹ ti tó!Ọlọ́run! Kí gbogbo ọmọ ènìyàn lesá sí abẹ́ òjijì ìyẹ́ Rẹ.

8. Àsè ilé Rẹ yóò tẹ́ wọn lọ́rùngidigidi; ìwọ yóò sì mú wọn munínú odò inú-dídùn Rẹ.

9. Nítorí pé pẹ̀lú ù Rẹ ni orísun ìyè wà:nínú ìmọ́lẹ̀ Rẹ ni àwa yóò rí ìmọ́lẹ̀.

10. Mú ìṣeun ìfẹ́ ẹ Rẹ sí àwọn tí ó mọ̀ ọ́àti ìgbàlà Rẹ sí àwọn tí ó ní ìdúró ṣinṣin ọkàn!

11. Má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ agbéragakí ó wá sí orí mi,kí ọwọ́ àwọn ènìyànbúburú sí mi ni ipò.

12. Níbẹ̀ ni àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀gbé subú sí:a Rẹ̀ wọ́n sílẹ̀,wọn kì yóò le è dìde!

Ka pipe ipin Sáàmù 36