Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 36:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìrékọjá sọ̀rọ̀ sí ènìyàn búburújinlẹ̀ nínú ọkàn wọn;Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò síníwájú ojú wọn

2. Nítorí pé wọ́n pọ́n ara wọn ní ojú ara wọntítí tí a kò fi le rí ẹ̀ṣẹ̀ wọn láti kórìíra.

3. Ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ni ẹ̀ṣẹ̀ òun ẹ̀tàn;wọ́n ti fi ọgbọ́n àti ṣíṣe rere sílẹ̀;

4. Wọ́n gbìmọ̀ ìwà ìkànígbà tí wọ́n wà lórí ibùsùn wọn:wọ́n gba ọ̀nà tí kò dára:wọn kò sì kọ ọ̀nà ibi sílẹ̀.

5. Ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ Rẹ,ìwọ Olúwa,ó ga dé ọ̀run,òtítọ́ ọ̀ Rẹ ga dé àwọ̀sánmà.

6. Òdodo Rẹ dàbí àwọn òkè Ọlọ́run,àwọn ìdájọ́ Rẹ dàbí ibú ńlá;ìwọ gba ẹranko àti ènìyàn là, Olúwa.

7. Báwo ni ìṣeun ìdúróṣinṣin ìfẹ́ Rẹ ti tó!Ọlọ́run! Kí gbogbo ọmọ ènìyàn lesá sí abẹ́ òjijì ìyẹ́ Rẹ.

8. Àsè ilé Rẹ yóò tẹ́ wọn lọ́rùngidigidi; ìwọ yóò sì mú wọn munínú odò inú-dídùn Rẹ.

Ka pipe ipin Sáàmù 36