Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 35:22-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Ìwọ́ ti ríiÌwọ Olúwa:Má ṣe dákẹ́!Ìwọ Olúwa,Má ṣe jìnnà sí mi!

23. Jí dìde!Ru ara Rẹ̀ sókè fún ààbò mi,fún ìdí mi,Ọlọ́run mi àti Olúwa mi!

24. Dá mi láre,ìwọ Olúwa,Ọlọ́run mi,gẹ́gẹ́ bí òdodo Rẹ,kí o má sì ṣe jẹ́ kíwọn kí ó yọ̀ lórí mi!

25. Má ṣe jẹ́ kí wọn wínínú ara wọn pé,“Áà! Àti rí ohun tí ọkànwa ń fẹ́:Má ṣe jẹ kí wọn kí ó wí pé,a ti gbé e mì.”

26. Kí ojú kí ó tì wọ́n,lí wọn kí ó sì dààmú pọ̀,tí ń yọ̀ sí ìyọnu mikí a fi ìtìjú àti àbùkù wọ̀ wọ́n ní aṣọtí ń gbéraga sí mi.

27. Jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ ìdáláre mifó fún ayọ̀ àti ìdùnnú,kí wọn máa sọ ọ́ titi lọ,pé gbígbéga ni “Olúwasí àlàáfíà ìránṣẹ Rẹ̀”.

Ka pipe ipin Sáàmù 35