4. Èmi wá Olúwa, ó sì dá mi lóhùn;Ó sì gbà mí kúrò nínú ìbẹ̀rù mi gbogbo.
5. Wọ́n wòó, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ wọn;ojú kò sì tì wọ́n
6. Ọkùnrin olùpọ́njú yí kígbe, Olúwa sì gbóhùn Rẹ̀;ó sì gbà á là kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú Rẹ̀.
7. Ángẹ́lì Olúwa yí àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀ káó sì gbà wọ́n.
8. Tọ́ ọ wò kí o sì rí i wí pé Olúwa dára;ẹni ayọ̀ ni ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ààbò nínú Rẹ̀.
9. Ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ̀yin ènìyàn Rẹ̀ mímọ́,nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀.
10. Àwọn ọmọ kìnnìún a máa ṣe aláìní ebi a sì máa pa wọ́n;ṣùgbọ́n àwọn tí ó wá Olúwa kì yóò ṣe aláìní ohun tí ó dára.
11. Wá, ẹ̀yin ọmọ mi, fi etí sí mi;èmi yóò kọ́ ọ yín ní ẹ̀rù Olúwa.
12. Taa ni nínú yín tí ń fẹ́ ìyè, tí ó sì ń fẹ́ ọjọ́ púpọ̀;kí ó lè gbádùn ọjọ́ rere?