Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 34:15-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo;etí i Rẹ̀ sì sí sí ẹkún wọn.

16. Ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú;láti ké ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.

17. Nígbà tí Olódodo bá ké fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa a máa gbọ́, a sì yọ wọ́n jáde láti inú gbogbo wàhálà wọn.

18. Olúwa sún mọ́ etí ọ̀dọ̀ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn;ó sì gba irú àwọn tí i ṣe oníròra ọkàn là.

Ka pipe ipin Sáàmù 34