Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 34:12-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Taa ni nínú yín tí ń fẹ́ ìyè, tí ó sì ń fẹ́ ọjọ́ púpọ̀;kí ó lè gbádùn ọjọ́ rere?

13. Pa ahọ́n Rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibiàti ètè Rẹ̀ kúrò ní ẹ̀tàn sísọ.

14. Yà kúrò nínú ibi kí o sì ṣe rere;wá àlàáfíà, kí o sì lépa Rẹ̀.

15. Ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo;etí i Rẹ̀ sì sí sí ẹkún wọn.

16. Ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú;láti ké ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.

Ka pipe ipin Sáàmù 34