Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 34:10-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Àwọn ọmọ kìnnìún a máa ṣe aláìní ebi a sì máa pa wọ́n;ṣùgbọ́n àwọn tí ó wá Olúwa kì yóò ṣe aláìní ohun tí ó dára.

11. Wá, ẹ̀yin ọmọ mi, fi etí sí mi;èmi yóò kọ́ ọ yín ní ẹ̀rù Olúwa.

12. Taa ni nínú yín tí ń fẹ́ ìyè, tí ó sì ń fẹ́ ọjọ́ púpọ̀;kí ó lè gbádùn ọjọ́ rere?

13. Pa ahọ́n Rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibiàti ètè Rẹ̀ kúrò ní ẹ̀tàn sísọ.

14. Yà kúrò nínú ibi kí o sì ṣe rere;wá àlàáfíà, kí o sì lépa Rẹ̀.

15. Ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo;etí i Rẹ̀ sì sí sí ẹkún wọn.

16. Ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú;láti ké ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.

17. Nígbà tí Olódodo bá ké fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa a máa gbọ́, a sì yọ wọ́n jáde láti inú gbogbo wàhálà wọn.

Ka pipe ipin Sáàmù 34