Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 34:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èmi yóò máa fi ìbùkún fún Olúwa nígbà gbogbo;ìyìn Rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi títí láé.

2. Ọkàn mí yóò máa ṣògo nínú Olúwa;jẹ́ kí àwọn onírẹ̀lẹ̀ gbọ́ kí inú wọn kí ó sì máa dùn.

3. Gbé Olúwa ga pẹ̀lú mi;kí ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ Rẹ̀ lékè.

4. Èmi wá Olúwa, ó sì dá mi lóhùn;Ó sì gbà mí kúrò nínú ìbẹ̀rù mi gbogbo.

5. Wọ́n wòó, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ wọn;ojú kò sì tì wọ́n

6. Ọkùnrin olùpọ́njú yí kígbe, Olúwa sì gbóhùn Rẹ̀;ó sì gbà á là kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú Rẹ̀.

7. Ángẹ́lì Olúwa yí àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀ káó sì gbà wọ́n.

8. Tọ́ ọ wò kí o sì rí i wí pé Olúwa dára;ẹni ayọ̀ ni ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ààbò nínú Rẹ̀.

9. Ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ̀yin ènìyàn Rẹ̀ mímọ́,nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀.

10. Àwọn ọmọ kìnnìún a máa ṣe aláìní ebi a sì máa pa wọ́n;ṣùgbọ́n àwọn tí ó wá Olúwa kì yóò ṣe aláìní ohun tí ó dára.

11. Wá, ẹ̀yin ọmọ mi, fi etí sí mi;èmi yóò kọ́ ọ yín ní ẹ̀rù Olúwa.

Ka pipe ipin Sáàmù 34