Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 33:12-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ìbùkún ni fún orílẹ̀ èdè náà Ọlọ́run ẹni tí Olúwa jẹ́ tirẹ̀,àti àwọn ènìyàn náà tí ó ti yàn ṣe ìní Rẹ̀.

13. Olúwa wò láti ọ̀run wá;Ó sì rí gbogbo ìran ènìyàn.

14. Níbi tí ó ti jókòó lóríi ìtẹ́Ó wo gbogbo àwọn olùgbé ayé

15. ẹni tí ó ṣe àyà wọn bákan náà,ó sì kíyèsí ìṣe wọn.

16. A kò gba ọba kan là nípaṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ogun;kò sì sí jagunjagun tí a gbà sílẹ̀ nípa agbára ńlá Rẹ̀.

17. Ohun asán ni ẹṣin fún ìsẹ́gun;bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi agbára ńlá Rẹ̀ gba ni sílẹ̀.

18. Wòó ojú Olúwa wà lára àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀,àti lára àwọn tí ó ní ìrètí nínú ìfẹ Rẹ̀ tí ó dúró ṣinṣin,

19. Láti gba ọkàn wọn kúrò lọ́wọ́ ikúàti láti pa wọ́n mọ́ láàyè lọ́wọ́ ìyàn.

20. Ọkàn wa dúró de Olúwa;òun ni ìrànlọ́wọ́ wa àti aṣà wa.

21. Ọkàn wa yọ̀ nínú Rẹ̀,nítorí pé, àwa gba orúkọ mímọ́ Rẹ̀ gbọ́

22. Kí àánú Rẹ, Olúwa, kí ó wà lára wa,àní gẹ́gẹ́ bí àwa ti ń ṣe ìrètí nínú Rẹ.

Ka pipe ipin Sáàmù 33