12. Ìbùkún ni fún orílẹ̀ èdè náà Ọlọ́run ẹni tí Olúwa jẹ́ tirẹ̀,àti àwọn ènìyàn náà tí ó ti yàn ṣe ìní Rẹ̀.
13. Olúwa wò láti ọ̀run wá;Ó sì rí gbogbo ìran ènìyàn.
14. Níbi tí ó ti jókòó lóríi ìtẹ́Ó wo gbogbo àwọn olùgbé ayé
15. ẹni tí ó ṣe àyà wọn bákan náà,ó sì kíyèsí ìṣe wọn.
16. A kò gba ọba kan là nípaṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ogun;kò sì sí jagunjagun tí a gbà sílẹ̀ nípa agbára ńlá Rẹ̀.
17. Ohun asán ni ẹṣin fún ìsẹ́gun;bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi agbára ńlá Rẹ̀ gba ni sílẹ̀.
18. Wòó ojú Olúwa wà lára àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀,àti lára àwọn tí ó ní ìrètí nínú ìfẹ Rẹ̀ tí ó dúró ṣinṣin,
19. Láti gba ọkàn wọn kúrò lọ́wọ́ ikúàti láti pa wọ́n mọ́ láàyè lọ́wọ́ ìyàn.
20. Ọkàn wa dúró de Olúwa;òun ni ìrànlọ́wọ́ wa àti aṣà wa.