Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 33:11-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ìgbìmọ̀ Olúwa dúró títí ayérayé,àní ìrò inú Rẹ̀ láti ìrandíran ni.

12. Ìbùkún ni fún orílẹ̀ èdè náà Ọlọ́run ẹni tí Olúwa jẹ́ tirẹ̀,àti àwọn ènìyàn náà tí ó ti yàn ṣe ìní Rẹ̀.

13. Olúwa wò láti ọ̀run wá;Ó sì rí gbogbo ìran ènìyàn.

14. Níbi tí ó ti jókòó lóríi ìtẹ́Ó wo gbogbo àwọn olùgbé ayé

15. ẹni tí ó ṣe àyà wọn bákan náà,ó sì kíyèsí ìṣe wọn.

16. A kò gba ọba kan là nípaṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ogun;kò sì sí jagunjagun tí a gbà sílẹ̀ nípa agbára ńlá Rẹ̀.

17. Ohun asán ni ẹṣin fún ìsẹ́gun;bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi agbára ńlá Rẹ̀ gba ni sílẹ̀.

18. Wòó ojú Olúwa wà lára àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀,àti lára àwọn tí ó ní ìrètí nínú ìfẹ Rẹ̀ tí ó dúró ṣinṣin,

19. Láti gba ọkàn wọn kúrò lọ́wọ́ ikúàti láti pa wọ́n mọ́ láàyè lọ́wọ́ ìyàn.

Ka pipe ipin Sáàmù 33