Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 32:3-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Nígbà tí mo dákẹ́,egungun mi di gbígbó dànùnípa ìkérora mi ní gbogbo ọjọ́.

4. Nítorí pé ni ọ̀sán àti ní òruọwọ́ Rẹ̀ wúwo sími lára;agbára mi gbẹ tángẹ́gẹ́ bí ooru ẹ̀ẹ̀rùn Sela

5. Èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọàti pé èmi kò sì fi àìsòdodo mi pamọ́.Èmi wí pé, “Èmi yóò jẹ́wọ́ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Olúwa,”ìwọ sì dáríẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jìn mí. Sela

6. Nítorí náà jẹ́ kí gbogbo àwọn olódodo máa gbà àdúrà sí ọní ìgbà tí a le ri ọ;nitòótọ́ nígbà tí ìṣàn omi ńlá bá ru sókè,wọn kì yóò le dé ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

7. Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi;ìwọ yóò pa mí mọ́ kúrò nínú ìyọnu;ìwọ yóò fi orin ìgbàlà yí mi ka. Sela

Ka pipe ipin Sáàmù 32