Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 32:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìbùkún ni fún àwọntí a dárí ìrékọjá wọn jìn,tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.

2. Ìbùkún ni fún ọkùnrin náàẹni tí Ọlọ́run kò ka ẹ̀ṣẹ̀ Rẹ̀ sí i lọ́rùnàti nínú ẹ̀mí ẹni tí kò sí ẹ̀tàn.

3. Nígbà tí mo dákẹ́,egungun mi di gbígbó dànùnípa ìkérora mi ní gbogbo ọjọ́.

4. Nítorí pé ni ọ̀sán àti ní òruọwọ́ Rẹ̀ wúwo sími lára;agbára mi gbẹ tángẹ́gẹ́ bí ooru ẹ̀ẹ̀rùn Sela

5. Èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọàti pé èmi kò sì fi àìsòdodo mi pamọ́.Èmi wí pé, “Èmi yóò jẹ́wọ́ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Olúwa,”ìwọ sì dáríẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jìn mí. Sela

6. Nítorí náà jẹ́ kí gbogbo àwọn olódodo máa gbà àdúrà sí ọní ìgbà tí a le ri ọ;nitòótọ́ nígbà tí ìṣàn omi ńlá bá ru sókè,wọn kì yóò le dé ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

7. Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi;ìwọ yóò pa mí mọ́ kúrò nínú ìyọnu;ìwọ yóò fi orin ìgbàlà yí mi ka. Sela

8. Èmi yóò kọ́ ọ, èmi yóò sì fi ẹsẹ̀ Rẹ lé ọ̀nà ìwọ yóò rìnèmi yóò máa gbà ọ ní ìyànjú, èmi yóò sì máa fi ojú mi tọ́ ọ.

9. Má ṣe dàbí ẹsin tàbí ìbaka,tí kò ní òyeẹnu ẹni tí a gbọdọ̀ fi ìjánu bọ̀,kí wọn má ba à sún mọ́ ọ.

10. Ọ̀pọ̀ ìkáàánú ní yóò wà fún ènìyàn búburú,ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa tí ó dúró ṣinṣinni yóò yí àwọn tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ká.

Ka pipe ipin Sáàmù 32