Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 31:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nínú Rẹ̀, Olúwa ni mo ti rí ààbò;Má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí;gbà mí nínú òdodo Rẹ.

2. Tẹ́ etí Rẹ sí mi,gbà mí kíákíá;jẹ́ àpáta ààbò mi,jẹ́ odi alágbára láti gbà mí.

3. Ìwọ pàápàá ni àpáta àti ààbò mi,nítorì orúkọ Rẹ máa ṣe ìtọ́ mi tọ́ mi kí o sì ṣe amọ̀nà mi.

4. Yọ mí jáde kúrò nínú àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ fún mi,nítorí ìwọ ni ìsádi mi.

5. Ní ọwọ́ Rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé;ìwọ ni ó tí rà mí padà, Olúwa, Ọlọ́run òtítọ́.

Ka pipe ipin Sáàmù 31