Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 30:6-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ní ìgbà ayé mi, mo wí pé,“a kì yóò sí mi nípò padà.”

7. Nípa ojúrere Rẹ̀, Olúwa,ìwọ ti gbé mi kalẹ̀ bí òkè tí ó ní agbára;ìwọ pa ojú Rẹ mọ́,àyà sì fò mí.

8. Sí ọ Olúwa, ni mo képè;àti sí Olúwa ni mo sunkún fún àánú:

9. “Èrè kí ni ó wà nínú ikú ìparun mi,nínú lílọ sí ihò mi?Eruku yóò a yìn ọ́ bí?Ǹjẹ́ yóò sọ nípa òdodo Rẹ?

10. Gbọ́, Olúwa, kí o sì ṣàánú fún mi;ìwọ Olúwa, jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi.”

11. Ìwọ ti yí ìkáànú mi di ijó fún mi;ìwọ sì ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ mi, o sì fi aṣọ ayọ̀ wọ̀ mí,

12. nítorí ìdí èyí ni kí ọkàn mi máa yìn ọ́, kí ó má sì ṣe dákẹ́.Ìwọ Olúwa Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ títí láé.

Ka pipe ipin Sáàmù 30