Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 30:5-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Nitorí pé ìbínú Rẹ̀ wà fún ìgbà díẹ̀,ojúrere Rẹ̀ wà títí ayeraye;Ẹkún lè pẹ́ títí di alẹ́,Ṣùgbọ́n ayọ̀ yóò wá ní òwúrọ̀.

6. Ní ìgbà ayé mi, mo wí pé,“a kì yóò sí mi nípò padà.”

7. Nípa ojúrere Rẹ̀, Olúwa,ìwọ ti gbé mi kalẹ̀ bí òkè tí ó ní agbára;ìwọ pa ojú Rẹ mọ́,àyà sì fò mí.

8. Sí ọ Olúwa, ni mo képè;àti sí Olúwa ni mo sunkún fún àánú:

9. “Èrè kí ni ó wà nínú ikú ìparun mi,nínú lílọ sí ihò mi?Eruku yóò a yìn ọ́ bí?Ǹjẹ́ yóò sọ nípa òdodo Rẹ?

10. Gbọ́, Olúwa, kí o sì ṣàánú fún mi;ìwọ Olúwa, jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi.”

Ka pipe ipin Sáàmù 30