Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 3:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa, báwo ni àwọn ọ̀ta mi ṣe pọ̀ tó!Báwo ni àwọn ti ó dìde sí mi ṣe pọ̀ tó!

2. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ń sọ ní ti tèmi, pé“Ọlọ́run kò ní gbà á là.”

3. Ṣùgbọ́n ìwọ ni àṣà yí mi ká, Olúwa;iwọ fi ogo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè.

4. Olúwa ni mo kígbe sókè sí,ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ Rẹ̀ wá.

5. Èmi dúbùú lẹ̀, mo sì sùn;mo sì tún padà jí, nítorí Olúwa ni ó ń gbé mi ró.

6. Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàntí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká.

Ka pipe ipin Sáàmù 3