Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 29:2-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Fi fún Olúwa, àní ògo orúkọ Rẹ̀;sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́.

3. Ohùn Olúwa ré àwọn omi kọjá;Ọlọ́run ògo sán àrá, Olúwa náà, alágbára ń bẹ lóríi omi púpọ̀.

4. Ohùn Olúwa ní agbára;ohùn Olúwa kún fún ọláńlá.

5. Ohùn Olúwa fọ́ igi kédárì; Olúwa náà ló fọ́ igi kédárì Lébánónì.

6. Ó mú Lébánónì fo bí i ọmọ màlúù,àti Síríónì bí ọmọ àgbáǹréré.

7. Ohùn Olúwa ń yabí ọwọ́ iná mọ̀nà

8. Ohùn Olúwa ń mi ihà. Olúwa mi ihà Kádéṣì.

9. Ohùn Olúwa ní ó lọ igi óákù, ó n mú abo àgbọ̀rín bíó sì bọ́ igi igbó sí ìhòòhò.àti nínú tẹ́ḿpìlì Rẹ̀ gbogbo ohùn wí pé “Ògo!”

10. Olúwa jókòó, Ó sì jọba lórí ìṣàn omi; Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọbatítí láéláé.

11. Kí Olúwa fi agbára fún àwọn ènìyàn Rẹ̀;bùkún àwọn ènìyàn Rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà.

Ka pipe ipin Sáàmù 29