1. Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ìran ọ̀run,Ẹ fi fún Olúwa, ògo àti agbára.
2. Fi fún Olúwa, àní ògo orúkọ Rẹ̀;sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́.
3. Ohùn Olúwa ré àwọn omi kọjá;Ọlọ́run ògo sán àrá, Olúwa náà, alágbára ń bẹ lóríi omi púpọ̀.
4. Ohùn Olúwa ní agbára;ohùn Olúwa kún fún ọláńlá.
5. Ohùn Olúwa fọ́ igi kédárì; Olúwa náà ló fọ́ igi kédárì Lébánónì.