Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 28:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìwọ Olúwa, mo képe àpáta mi;Má ṣe kọ eti dídi sí mi.Tí ìwọ bá dákẹ́ sí mi,èmí yóò dàbí àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun.

2. Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú,bí mo ṣe ń ké pé ọ́ fún ìràn lọ́wọ́,bí mo ṣe gbé àwọn ọwọ́ mi sókèsí ibi mímọ́ Rẹ jùlọ.

3. Má ṣe fà mí lọ pẹ̀lú ènìyàn búburú àti,pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,tí ń sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò wọnṣùgbọ́n tí ìwà ìkà ń bẹ nínú wọn.

4. Ṣan ẹ̀ṣan wọn gẹ́gẹ́ bí isẹ́ wọnàti fún iṣẹ́ ibi wọn;gba ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn;kí o sì san ẹ̀ṣan wọn bí ó ti tọ́.

5. Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí,tàbí àwọn isẹ́ ọwọ́ Rẹ̀òun ó rún wọn wọlẹ̀kò sì ní tún wọn kọ́ mọ́.

6. Alábùkún fún ni Olúwa!Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.

7. Olúwa ni agbára mi àti aṣà mi;nínú Rẹ̀ ni mo gbẹ́kẹ̀lé; àní, ó sì ràn mí lọ́wọ́.ọkàn mi sì gbé sókè fún ayọ̀àni pẹ̀lú orin mi mo fi ọpẹ́ fún un.

8. Olúwa ni agbára àwọn ènìyàn Rẹ̀òun ni odi ìgbàlà àwọn àyànfẹ́ẹ Rẹ̀.

9. Ìwọ gba àwọn ènìyàn Rẹ là, kí o sì bùkún àwọn ajogún Rẹ;di olùsọ́ àgùntàn wọn, kí o sì gbé wọn lékè títí ayérayé.

Ka pipe ipin Sáàmù 28