Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 27:9-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Má ṣe fi ojú Rẹ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi,má ṣe fi ìbínú ṣá ìránṣẹ́ Rẹ tì;ìwọ tí o ti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi,Má ṣe ju mi sílẹ̀, má si ṣe kọ̀ mí,áà Ọlọ́run ìgbàlà mi.

10. Bí ìyá àti bàbá bá kọ̀ mí sílẹ̀, Olúwa yóò tẹ́wọ́ gbà mí.

11. Kọ́ mi ní ọ̀nà Rẹ, Olúwa,kí o sì sìn mi lọ sí ọ̀nà tí ó tẹ́júnítorí àwọn ọ̀tá mi.

Ka pipe ipin Sáàmù 27