Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 27:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi;ta ni èmi yóò bẹ̀rù? Olúwa ni ibi olódì ẹ̀mí mi,ta ni ẹni tí èmi yóò bẹ̀rù?

2. Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú kọjú ìjà sí miláti jẹ ẹran ara mi,àní àwọn ọ̀ta mi àti àwọn abínúkú ù mi,wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.

3. Bí ọmọ ogun tilẹ̀ yí mi ká tí wọ́n sì dìde sí mi,ọkàn mi kì yóò bẹ̀rù;bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi,nínú èyí ni ọkàn mi yóò le.

4. Ohun kan ni mo bèèrè nípasẹ̀ Olúwa,òun ni èmi yóò máa wá kiri:kí èmi kí ó le wà ní ilé Olúwaní ọjọ́ ayé mi gbogbo,kí èmi: kí ó le kíyèsí ẹwà Olúwa,kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹ́ḿpìlì Rẹ.

5. Nítorí pé ní ìgbà ìpọ́njúòun yóò pa mí mọ́ nínú àgọ́ Rẹ̀;níbi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ Rẹ̀ ni òun yóò pa mí mọ́;yóò sì gbé mi sókè lórí àpáta.

Ka pipe ipin Sáàmù 27