Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 26:6-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Èmí ó wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì yí pẹpẹ Rẹ ká Olúwa

7. Èmi yóò kọrin sókè àní orin ọpẹ́,èmi yóò sì máa sọ iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀.

8. Áà Olúwa, èmí ń fẹ́ ilé Rẹ ní bi tí ìwọ ń gbé,àní níbi tí àgọ́ ọlá Rẹ̀ wà.

9. Má ṣe gbá mi dànù pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,tàbí ẹ̀mí mi pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ,

10. Àwọn tí ọwọ́ wọn kún fún ìwà ibi,tí ọwọ́ ọ̀tún wọn kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀.

11. Ṣùgbọ́n èmi ó máa rìn nínú ìwà títọ́;rà mí padà, kí o sì ṣàánú fún mi.

12. Ẹsẹ̀ mi dúró lórí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú;nínú ìjọ ńlá èmi yóò fi ìbùkún fún Olúwa.

Ka pipe ipin Sáàmù 26