Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 26:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa,nítorí tí mo ti ń rìn nínú ìwà òtítọ́ ọ̀ mi,mo sì ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú OlúwaǸjẹ́ ẹsẹ̀ mi kì yóò yẹ̀.

2. Wádìí mi wò, Ìwọ Olúwa, kí o sì dán mi wò,dán àyà àti ọkàn mi wò;

3. Nítorí ìfẹ́ ẹ̀ Rẹ tí ó dúró ṣinṣin ń bẹ níwájú mi,èmí sì ti rìn nínú òtítọ́ Rẹ.

4. Èmi kò jókòó pẹ̀lú aláìsòótọ́,bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá àwọn àgàbàgebè wọlé;

5. Èmi ti kórìírá àwùjọ àwọn ènìyàn búburúèmi kì yóò sì bá àwọn ènìyàn ìkà jókòó.

Ka pipe ipin Sáàmù 26