Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 25:5-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. ṣe amọ̀nà mi nínú ọ̀títọ́ ọ Rẹ, kí ò si kọ́ mi,Nítoríi ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi;ìwọ ni mo dúró tì ní gbogbo ọjọ́.

6. Rántí, áà! Olúwa àánú àti ìfẹ́ ẹ̀ Rẹ̀ ńlá,torí pé wọ́n ti wà ní ìgbà àtijọ́

7. Má ṣe rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mitàbí ìrékọjáà mi;gẹ́gẹ́ bí i ìfẹ́ ẹ Rẹ̀ rántíì minítorí tí ìwọ dára, Ìwọ! Olúwa.

8. Rere àti ẹni ìdúró ṣinṣin ní Olúwa:nítorí náà ó kọ́ àwọn ẹlẹ́sẹ̀ ni ọ̀nà náà.

9. Ó ṣe amọ̀nà àwọn onírẹ̀lẹ̀ ni ohun tí ó dára,ó sì kọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ ní ọ̀nà Rẹ̀.

10. Gbogbo ipa ọ̀nà Olúwa ni ìfẹ́ àti òdodo tí ó dúró ṣinṣin,fún àwọn tí ó pa májẹ̀mú àti ẹ̀rí Rẹ̀ mọ́.

11. Nítorí orúkọ Rẹ̀, áà! Olúwa,dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jìn mí, nítorí tí ó tóbi.

12. Àwọn wo ni ó bẹ̀rù Olúwa?Yóò kọ wọn ní ọ̀nà èyí tí wọn yóò yàn.

13. Wọn yóò lo ọjọ́ wọn nínú àlàáfíà,àwọn ọmọ wọn yóò sì gba ilẹ̀ náà.

14. Olúwa fi ọkàn tán, àwọn tí o bẹ̀rù u Rẹ̀;ó sọ májẹ̀mú Rẹ̀ di mímọ̀ fún wọn.

15. Ojú mi gbé sókè sọ́dọ̀ Olúwa,nítorí pé yóò yọ ẹsẹ̀ mi kúrò nínú àwọ̀n náà.

Ka pipe ipin Sáàmù 25