Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 24:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ti Olúwa ni ilẹ̀, àti ẹ̀kún Rẹ̀,ayé àti àwọn tí ó tẹ̀dó sínú Rẹ̀;

2. Nítorí ó fi ìpìlẹ̀ Rẹ̀ lélẹ̀ lórí òkunó sì gbée kalẹ̀ lórí àwọn ìṣàn omi.

3. Ta ni yóò gun òrí òkè Olúwa lọ?Ta ni yóò dúró ní ibi mímọ́ Rẹ̀?

4. Ẹni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun,ẹni tí kò gbé ọkàn Rẹ̀ sókè sí asántí kò sì búra èké.

5. Òun ni yóò rí ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa,àti òdodo lọ́wọ́ Ọlọ́run ìgbàlà Rẹ̀.

6. Èyí ni ìran àwọn tí ń ṣe àfẹ́rí Rẹ̀,tí ń ṣe àfẹ́rí Rẹ̀, Ọlọ́run Jákọ́bù. Sela

7. Ẹ gbé orí yín sókè, Áà! Ẹ̀yin ọ̀nà;Kí á sì gbe yín sókè, áà! Ẹyin ilẹ̀kùn ayérayé!Kí ọba ògo le è wọlé.

8. Ta ni ọba ògo náà? Olúwa tí ó lágbára tí ó sì le, Olúwa gan-an, tí o lágbára ní ogun.

Ka pipe ipin Sáàmù 24