Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 22:1-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?Èéṣe tí o fi jìnnà láti gbà mí là,àní sí igbe àwọn asọ̀ mi?

2. Ọlọ́run mi, ní ọ̀sán gangan ni mo kígbe, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi ní ohùn:àti ní òru èmi kò dákẹ́.

3. Ṣùgbọ́n ṣíbẹ̀ ẹni mímọ́ ni ìwọ;ẹni tí ó tẹ ìyìn Ísírẹ́lì dó;

4. Àwọn babańlá wa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú un Rẹ;wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ìwọ sì gbà wọ́n.

5. Ìwọ ni wọ́n sun ẹkún sí, wọ́n sì ní ìgbàlà;ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀lé, a kò sì dójú tì wọ́n.

6. Ṣùgbọ́n kòkòrò ní mo jẹ́ kì í sì í ṣe ènìyàn;mo di ẹlẹ́gàn àwọn ènìyàn ẹlẹ́yà àwọ́n ènìyàn

7. Gbogbo àwọn tí ó rí mí fi mí ṣe ẹlẹ́yà;wọ́n yọ ètè ẹ̀gàn wọn sí mi, wọ́n sì ń mi orí i wọn pé.

8. “Ó gbẹkẹ Rẹ̀ lé Olúwa;jẹ́ kí Olúwa gbà á là.Jẹ́ kí ó gbà a là,nítorí pé ó ni ayọ̀ nínú Rẹ̀.”

9. Ṣíbẹ̀ ìwọ ni ó ti mú mi wá láti inú;ìwọ ni ó mú mi wà láìléwunígbà tí mo rọ̀ mọ́ ọmú ìyá mi.

10. Ìwọ ni a fi mí lé lọ́wọ́ láti inú ìyá mi wánígbà tí ìyá a mí sì ti bí mi, ìwọ ni Ọlọ́run mi

11. Má ṣe jìnnà sími,nítorí pé ìyọnu sún mọ́ tòsíkò sì sí ẹnìkan tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́.

12. Ọ̀pọ̀ akọ màlúù yí mi ká;àwọn màlúù alágbára Báṣánì rọ̀gbà yí mi ká.

13. wọ́n ya ẹnu wọn, si mi bí i kìn-nìún tí ń dọdẹ kirití ń ké ramúramù.

14. A dà mí jáde gẹ́gẹ́ bí omi,gbogbo egungun mi ti yẹ̀ kúrò ní oríkèé Rẹ̀.Ọkàn mi sì dàbí i ìda;tí ó yọ́ láàrin inú un mi.

15. Agbára mí ti gbẹ bí àpáàdì,ahọ́n mí sì ti lẹ̀ mọ́ párí ẹ̀rẹ̀kẹ́ ẹ mi;ìwọ ti tẹ́ mi sínú eruku ikú.

16. Àwọn ajá yí mi ká;ọwọ́ àwọn ènìyàn ibi ti ka mi mọ́,Wọ́n gún mi lọ́wọ́, wọ́n sì gún mi lẹ́ṣẹ̀

17. Mo lè ka gbogbo àwọn egungun mi;àwọn tìkára wọn ń wò, wọ́n dójú lé mi.

18. Wọ́n pín aṣọ mi láàrin ara wọnàní lórí aṣọ mi ni wọ́n ṣẹ́ gègé.

19. Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, má ṣe jìnnà sí mi;Áà Olùrànlọ́wọ́ ọ̀ mi, yára wa fún àtìlẹ́yìn mi!

20. Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ idà,àní ẹ̀mí mi lọ́wọ́ agbára àwọn ajá.

21. Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ ọ kìnnìún;Kí o sì gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ìwo àgbáǹréré.

Ka pipe ipin Sáàmù 22