Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 20:5-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Àwa yóò hó fún ayọ̀ nígbà tí o bá di aṣẹ́gunàwa yóò gbé àsíá wa sókè ní orúkọ Ọlọ́run wa.Kí Ọlọ́run kí ó mú gbogbo ìbéèrè Rẹ̀ ṣẹ.

6. Nisinsìnyí, èmi mọ̀ wí pé Olúwa pa ẹni-àmí-òróró Rẹ̀ mọ́;yóò gbọ́ láti ọ̀run mímọ́ Rẹ̀ wápẹ̀lú agbára ìgbàlà ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀.

7. Àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé kẹ̀kẹ́, àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé ẹṣin,ṣùgbọ́n àwa gbẹ́kẹ̀ lé orúkọ Olúwa Ọlọ́run wa.

8. Wọ́n wólẹ̀, ní eékún, wọn sì ṣubú,ṣùgbọ́n àwa dìde, a sì dúró ṣinṣin.

9. Olúwa, fi ìṣẹ́gun fún ọba!Dá wa lóhùn nígbà tí a bá ń kígbe pè!

Ka pipe ipin Sáàmù 20