Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 20:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Kí Olúwa kí ó gbóhùn Rẹ̀ ní ọjọ́ ìpọ́njú;kí orúkọ Ọlọ́run Jákọ́bù kí ó dáàbòbò ọ́.

2. Kí ó rán ìrànlọ́wọ́ sí ọ, láti ibi mímọ́kí ó sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Síónì wá.

3. Kí ó sì rántí gbogbo ẹbọ ọrẹ Rẹkí ó sì gba ẹbọ sísun un Rẹ. Sela

4. Kí ó fi fún ọ gẹ́gẹ́ bi ti èrò ọkàn Rẹkí ó sì mú gbogbo ìmọ̀ Rẹ ṣẹ.

5. Àwa yóò hó fún ayọ̀ nígbà tí o bá di aṣẹ́gunàwa yóò gbé àsíá wa sókè ní orúkọ Ọlọ́run wa.Kí Ọlọ́run kí ó mú gbogbo ìbéèrè Rẹ̀ ṣẹ.

6. Nisinsìnyí, èmi mọ̀ wí pé Olúwa pa ẹni-àmí-òróró Rẹ̀ mọ́;yóò gbọ́ láti ọ̀run mímọ́ Rẹ̀ wápẹ̀lú agbára ìgbàlà ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀.

Ka pipe ipin Sáàmù 20