Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 2:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èéṣe tí àwọn orílẹ̀ èdè fi ń dìtẹ̀,àti tí àwọn ènìyàn ń ṣe rìkísí asán?

2. Àwọn ọba ayé péjọ pọ̀àti àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀sí Olúwaàti sí Ẹni àmì òróró Rẹ̀.

3. Wọ́n sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a fa ẹ̀wọ̀n wọn já,”“kí a sì ju ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ wọn nù.”

4. Ẹni tí ó gúnwà lórí ìtẹ́ lọ́run rẹ́rìn-ín; Olúwa fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.

5. Nígbà náà ni ó bá wọn wí ní ìbínú Rẹ̀ó sì dẹ́rùba bà wọ́n ní ìrunú Rẹ̀, ó wí pé,

6. “Èmi ti fi ọba mi sí ipòlórí Síónì, òkè mímọ́ mi.”

7. Èmi yóò sì kéde ìpinnu Olúwa:Ó sọ fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi;lónìí, èmi ti di baba Rẹ.

8. Béèrè lọ́wọ́ mi,Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀ èdè di ìní Rẹ,òpin ilé ayé yóò sì jẹ́ ogún Rẹ.

9. Ìwọ yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọnìwọ yóò sì rún wọn wómú wómú bí ìkòkò amọ̀”.

10. Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ jẹ́ ọlọgbọ́n;ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ ẹ̀yin alákòóso ayé.

11. Ẹ ṣin Olúwa pẹ̀lú ìbẹ̀rùẹ sì máa yọ̀ pẹ̀lú ìwárìrì.

Ka pipe ipin Sáàmù 2