Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 19:4-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo orílẹ̀ ayéọ̀rọ̀ wọn títí dé òpin ilẹ̀ ayé,ó ti kọ́ àgọ́ fún oòrùn nínú àwọn ọ̀run.

5. Ti o dàbí ọkọ ìyàwó tí ó ń jáde ti yàrá Rẹ̀ wáÒun yọ bí alágbára ọkùnrin tí o ń sáré ìje.

6. Ìjáde lọ Rẹ̀ ni láti òpin ọ̀run wáàti àyíká Rẹ̀ sì dé ìpínlẹ̀ Rẹ̀;kò sì sí ohun tí ó pamọ́ kúrò nínú oore Rẹ̀.

7. Pípé ni òfin Olúwa,ó ń yí ọkàn padà.ẹ̀rí Olúwa dánilójú,ó sọ òpè di ọlọ́gbọ́n.

8. Ìlànà Olúwa tọ̀nà,ó ń fi ayọ̀ fún ọkàn.àṣẹ Olúwa ní mímọ́,ó ń fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú.

9. Ìbẹ̀rù Olúwa mọ́,ó ń faradà títí láéláé.Ìdájọ́ Olúwa dájúòdodo ni gbogbo wọn.

10. Wọn ṣọ̀wọ́n ju gólùù lọ,ju góòlù tí o dára jùlọ.wọ́n dùn ju oyin lọ,Àti ju afárá oyin lọ.

11. Nípa wọn ni a ti sí ìránṣẹ́ Rẹ̀ létí;nípa pípa wọ́n mọ́, èrè púpọ̀ ń bẹ.

12. Ta ni o lé mọ àṣìṣe Rẹ̀?Dáríjìn mí nínú àṣìṣe mi tí ó pamọ́.

13. Wẹ ìrànsẹ́ Rẹ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́n-mọ̀-dá;Má ṣe jẹ kí wọn kí ó jọba lórí mi.Nígbà náà ní èmí yóò dúró ṣinṣin,èmi yóò sì ṣe aláìlẹ́bi kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.

14. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn mikí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú Rẹ,Ìwọ Olúwa, àpáta mi.àti Olùdáǹdè mi.

Ka pipe ipin Sáàmù 19