Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 19:2-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Wọ́n ń fọhùn ní ọjọ́ dé ọjọ́;wọ́n ń fi ìmọ̀ hàn ní alẹ́ dé alẹ́.

3. Kò sí ohùn tàbí èdèníbi tí a kò gbé gbọ́ ìró wọn

4. Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo orílẹ̀ ayéọ̀rọ̀ wọn títí dé òpin ilẹ̀ ayé,ó ti kọ́ àgọ́ fún oòrùn nínú àwọn ọ̀run.

5. Ti o dàbí ọkọ ìyàwó tí ó ń jáde ti yàrá Rẹ̀ wáÒun yọ bí alágbára ọkùnrin tí o ń sáré ìje.

6. Ìjáde lọ Rẹ̀ ni láti òpin ọ̀run wáàti àyíká Rẹ̀ sì dé ìpínlẹ̀ Rẹ̀;kò sì sí ohun tí ó pamọ́ kúrò nínú oore Rẹ̀.

7. Pípé ni òfin Olúwa,ó ń yí ọkàn padà.ẹ̀rí Olúwa dánilójú,ó sọ òpè di ọlọ́gbọ́n.

8. Ìlànà Olúwa tọ̀nà,ó ń fi ayọ̀ fún ọkàn.àṣẹ Olúwa ní mímọ́,ó ń fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú.

9. Ìbẹ̀rù Olúwa mọ́,ó ń faradà títí láéláé.Ìdájọ́ Olúwa dájúòdodo ni gbogbo wọn.

10. Wọn ṣọ̀wọ́n ju gólùù lọ,ju góòlù tí o dára jùlọ.wọ́n dùn ju oyin lọ,Àti ju afárá oyin lọ.

11. Nípa wọn ni a ti sí ìránṣẹ́ Rẹ̀ létí;nípa pípa wọ́n mọ́, èrè púpọ̀ ń bẹ.

Ka pipe ipin Sáàmù 19