Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 19:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àwọn òrun ń sọ nípa ti ògo Ọlọ́run;Àwọ̀sánmọ̀ ń sọ nípa ti iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ̀.

2. Wọ́n ń fọhùn ní ọjọ́ dé ọjọ́;wọ́n ń fi ìmọ̀ hàn ní alẹ́ dé alẹ́.

3. Kò sí ohùn tàbí èdèníbi tí a kò gbé gbọ́ ìró wọn

4. Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo orílẹ̀ ayéọ̀rọ̀ wọn títí dé òpin ilẹ̀ ayé,ó ti kọ́ àgọ́ fún oòrùn nínú àwọn ọ̀run.

5. Ti o dàbí ọkọ ìyàwó tí ó ń jáde ti yàrá Rẹ̀ wáÒun yọ bí alágbára ọkùnrin tí o ń sáré ìje.

Ka pipe ipin Sáàmù 19