Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 18:5-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Okùn isà òkú yí mi ká,ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí.

6. Nínú ìpọ́njú mo ké pe Olúwa;Mo sunkún sí Olúwa mi fún ìrànlọ́wọ́.Láti inú tẹ́ḿpìlì Rẹ̀, ó gbọ́ igbe mi;ẹkún mi wá sí iwájú Rẹ̀, sí inú etí Rẹ̀.

7. Ayé wárìrì, ó sì mì tìtì pẹ̀lú,ìpìlẹ̀, àwọn òkè gíga sì sídìí;wọ́n wárìrì nítorí tí ó ń bínú.

8. Èéfín ti ihò imú Rẹ̀ jáde wá;Iná ajónirun ti ẹnu Rẹ̀ jáde wá,ẹ̀yin iná bú jáde láti inú Rẹ̀.

9. Ó pín àwọn ọ̀run, Ó sì jáde wá;àwọsánmọ̀ dúdú sì wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ Rẹ̀.

10. Ó gun orí kérúbù, ó sì fò;ó ń rá bàbà lórí ìyẹ́ apá afẹ́fẹ́.

11. Ó fi òkùnkùn ṣe ibojì Rẹ̀, ó fi ṣe ìbòrí yí ara Rẹ̀ kákùrúkùrù òjò dúdú ní ojú ọ̀run.

12. Nípa ìmọ́lẹ̀ iwájú Rẹ̀, àwọ̀sánmà ṣíṣú dudu Rẹ kọja lọpẹ̀lú yìnyín àti ẹyìn iná

13. Olúwa sán àrá láti ọ̀run wá;Ohùn ẹni gíga jùlọ tí ń dún.

14. Ó ta àwọn ọfà Rẹ̀, ó sì tú àwọn ọ̀ta náà ká,ọfà mọ̀nàmọ́ná ńlá sì dà wọ́n rú.

15. A sì fi ìṣàlẹ̀ àwọn òkun hàn,a sì rí àwọn ìpìlẹ̀ ayénípa ìbáwí Rẹ̀, Olúwa,nípa fífún èémí ihò imú Rẹ.

Ka pipe ipin Sáàmù 18