30. Bí ó ṣe ti Ọlọ́run mi, ọ̀nà Rẹ̀ pé,a ti rídìí ọ̀rọ̀ Olúwaòun ni àpáta ààbòfún gbogbo àwọn tí ó fi ṣe ààbò.
31. Nítorí ta ni ṣe Ọlọ́run bí kò ṣe Olúwa?Ta ní àpátà bí kò ṣe Olúwa wa?
32. Ọlọ́run ni ẹni tí ó fi agbára dì mí ní àmùrèó sì mú ọ̀nà mi pé.
33. Ó ṣe ẹsẹ̀ mi gẹ́gẹ́ bi ẹsẹ̀ àgbọ̀nrín;ó jẹ́ ki n lè dúró lórí ibi gíga.
34. Ó kọ́ ọwọ́ mi ni ogun jíja;apá mi lè tẹ ọrùn idẹ
35. Ìwọ fi àṣà ìṣẹ́gun Rẹ̀ fún mi,ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ gbé mí sókè;àti ìwà ìpẹ̀lẹ́ Rẹ̀ sọ mi di alágbára àti ẹni ńlá.
36. Ìwọ sọ ìrìn ẹsẹ mi di ńlá ní ìṣàlẹ̀ mi,kí kókó-ẹsẹ̀ mi má ṣe yẹ̀.
37. Èmi lépa àwọn ọ̀tá mi èmi sì bá wọnèmi kò sì padà lẹ́yìn wọn títí a fi run wọ́n.
38. Èmi ṣá wọn ní ọgbẹ́ tí wọn ko fi le è dìde;Wọ́n subú ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi.
39. Nítorí ìwọ fi agbára dì mí ní amùrè fún ogun náà;ìwọ ti mú àwọn tí ó dìde si mí tẹríba ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi
40. Ìwọ yí ẹ̀yìn àwọn ọ̀ta mí padà sí mièmi sì pa àwọn tí ó kóríra mí run.