Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 18:22-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Gbogbo òfin Rẹ̀ ni ó wà níwájú mi;èmi kò sì yípadà kúrò nínú ìlànà Rẹ̀.

23. Mo ti jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú Rẹ̀;mo sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.

24. Olúwa san ẹ̀ṣan fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi níwájú Rẹ̀.

25. Sí olóòótọ́ ìwọ ó fi ara Rẹ̀ hàn ní olóòtọ́,sí aláìlẹ́bi, ìwọ ó fi ara Rẹ̀ hàn ní aláìlẹ́bi,

26. Sí ọlọ́kan mímọ́, ìwọ ó fi ara Rẹ̀ hàn ní ọlọ́kàn mímọ́,ṣùgbọ́n sí ọlọ́kàn-wíwọ́, ìwọ ó fi ara Rẹ̀ hàn ní òǹrorò.

27. O pa onírẹ̀lẹ̀ mọ́,ṣùgbọ́n o Rẹ̀ àwọn ti ń gbéraga sílẹ̀.

28. Ìwọ, Olúwa, jẹ́ kí fìtílà mikí ó máa tàn; Ọlọ́run mi, yí òkùnkùn mi padà sí ìmọ́lẹ̀.

29. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀, èmi ṣare la ogun lọ;pẹ̀lú Ọlọ́run mi mo lè fo odi kan

30. Bí ó ṣe ti Ọlọ́run mi, ọ̀nà Rẹ̀ pé,a ti rídìí ọ̀rọ̀ Olúwaòun ni àpáta ààbòfún gbogbo àwọn tí ó fi ṣe ààbò.

31. Nítorí ta ni ṣe Ọlọ́run bí kò ṣe Olúwa?Ta ní àpátà bí kò ṣe Olúwa wa?

32. Ọlọ́run ni ẹni tí ó fi agbára dì mí ní àmùrèó sì mú ọ̀nà mi pé.

33. Ó ṣe ẹsẹ̀ mi gẹ́gẹ́ bi ẹsẹ̀ àgbọ̀nrín;ó jẹ́ ki n lè dúró lórí ibi gíga.

34. Ó kọ́ ọwọ́ mi ni ogun jíja;apá mi lè tẹ ọrùn idẹ

Ka pipe ipin Sáàmù 18