Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 18:15-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. A sì fi ìṣàlẹ̀ àwọn òkun hàn,a sì rí àwọn ìpìlẹ̀ ayénípa ìbáwí Rẹ̀, Olúwa,nípa fífún èémí ihò imú Rẹ.

16. Ó sọ̀kalẹ̀ láti ibi gíga ó sì dì mí mú;Ó fà mí jáde láti inú omi jínjìn.

17. Ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ ọ̀ta mi alágbára,láti ọwọ́ àwọn ọ̀ta, ti ó lágbára jù fún mi.

18. Wọ́n dojúkọ mí ní ọjọ́ ìpọ́njú mi;ṣùgbọ́n Olúwa ni alàtìlẹ́yìn mi.

19. Ó mú mi jáde wá sínú ibi ńlá;Ó gbà mí nítorí tí ó ní inúdídùn sí mi.

Ka pipe ipin Sáàmù 18