13. Olúwa sán àrá láti ọ̀run wá;Ohùn ẹni gíga jùlọ tí ń dún.
14. Ó ta àwọn ọfà Rẹ̀, ó sì tú àwọn ọ̀ta náà ká,ọfà mọ̀nàmọ́ná ńlá sì dà wọ́n rú.
15. A sì fi ìṣàlẹ̀ àwọn òkun hàn,a sì rí àwọn ìpìlẹ̀ ayénípa ìbáwí Rẹ̀, Olúwa,nípa fífún èémí ihò imú Rẹ.
16. Ó sọ̀kalẹ̀ láti ibi gíga ó sì dì mí mú;Ó fà mí jáde láti inú omi jínjìn.
17. Ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ ọ̀ta mi alágbára,láti ọwọ́ àwọn ọ̀ta, ti ó lágbára jù fún mi.
18. Wọ́n dojúkọ mí ní ọjọ́ ìpọ́njú mi;ṣùgbọ́n Olúwa ni alàtìlẹ́yìn mi.
19. Ó mú mi jáde wá sínú ibi ńlá;Ó gbà mí nítorí tí ó ní inúdídùn sí mi.