Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 16:4-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ìṣòro àwọn wọ̀n ọn nì yóò pọ̀ síiàwọn tí ń tọ ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn.Ẹbọ ohun mímu ẹ̀jẹ̀ wọn ni èmi kì yóò ta sílẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá orúkọ wọn lẹ́nu mi.

5. Olúwa, ni ìní mi tí mo yàn àti ago mi,ó ti pa ohun tí íṣe tèmi mọ́.

6. Okùn ààlà ilẹ̀ ti bọ́ sí ọ̀dọ̀ mi ní ibi dídára;nítòótọ́ mo ti ní ogún rere.

7. Èmi yóò yin Olúwa, ẹni tí ó gbàmí ní ìyànjú;ní òru, ọkàn mí ń bá mi sọ̀rọ̀.

8. Mo ti gbé Ọlọ́run ṣíwájú mi ní ìgbà gbogbo.Nítorí tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi,a kì yóò mì mí.

9. Nítorí èyí, ọkàn mi yọ̀, ahọ́n mi pẹ̀lú ń fò fáyọ̀;ara mi pẹ̀lú yóò sinmi ní ààbò,

10. nítorí ìwọ kò ní fi ọ̀kan sílẹ̀ nínú iṣà òkú,tàbí kí ìwọ jẹ́ kí ẹni mímọ́ Rẹ kí ó rí ìdíbàjẹ́.

11. Ìwọ ti fi ipa ọ̀nà ìyè hàn mí;Ìwọ yóò kún mi pẹ̀lú ayọ̀ ní ìwájú Rẹ,pẹ̀lú ìdùnnú ayérayé ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ.

Ka pipe ipin Sáàmù 16