Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 16:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Pa mí mọ́, Ọlọ́run,nítorí nínú Rẹ ni ààbò mí wà.

2. Mo sọ fún Olúwa, “ìwọ ni Ọlọ́run mi,lẹ́yìn Rẹ èmi kò ní ire kan.”

3. Sí àwọn ènìyàn tí ó wà ní ayé,àwọn ni ológo nínú èyí tí ayọ̀ mí wà.

4. Ìṣòro àwọn wọ̀n ọn nì yóò pọ̀ síiàwọn tí ń tọ ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn.Ẹbọ ohun mímu ẹ̀jẹ̀ wọn ni èmi kì yóò ta sílẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá orúkọ wọn lẹ́nu mi.

5. Olúwa, ni ìní mi tí mo yàn àti ago mi,ó ti pa ohun tí íṣe tèmi mọ́.

6. Okùn ààlà ilẹ̀ ti bọ́ sí ọ̀dọ̀ mi ní ibi dídára;nítòótọ́ mo ti ní ogún rere.

7. Èmi yóò yin Olúwa, ẹni tí ó gbàmí ní ìyànjú;ní òru, ọkàn mí ń bá mi sọ̀rọ̀.

8. Mo ti gbé Ọlọ́run ṣíwájú mi ní ìgbà gbogbo.Nítorí tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi,a kì yóò mì mí.

9. Nítorí èyí, ọkàn mi yọ̀, ahọ́n mi pẹ̀lú ń fò fáyọ̀;ara mi pẹ̀lú yóò sinmi ní ààbò,

Ka pipe ipin Sáàmù 16