Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 147:15-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Òun sì rán àṣẹ Rẹ̀ sí ayéọ̀rọ̀ Rẹ̀ sáré tete.

16. Ó fi sino fún ni bi irun àgùntànó sì fọ́n ìrì idídì ká bí eérú

17. Ó rọ òjò yìnyín Rẹ̀ bí òkúta wẹ́wẹ́ta ni ó lè dúró níwájú òtútù Rẹ̀

18. Ó rán ọ̀rọ̀ Rẹ̀ jáde ó sì mú wọn yọ̀ó mú kí afẹ́fẹ́ Rẹ̀ fẹ́ó sì mú odò Rẹ̀ sàn.

19. Ó sọ ọ̀rọ̀ Rẹ̀ di mímọ̀ fún Jákọ́bùàwọn òfin àti ìlànà Rẹ̀ fún Ísírẹ́lì

20. Òun kó tí ṣe irú èyí sí orílẹ̀ èdè kan rí, Bí ó ṣe ti ìdájọ́ Rẹ̀wọn ko mọ òfin Rẹ̀.Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ka pipe ipin Sáàmù 147